Zechariah 11:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó-ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó-ọ̀yà mi.