Zechariah 11:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.