Zechariah 12:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọ̀kọ, nwọn o si ma ṣọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi enia ti nṣọ̀fọ fun ọmọ ọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ ṣórí ilé Dáfídì àti sórí Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa sọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń sọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.