Zechariah 12:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀.