Zechariah 12:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na li Oluwa yio dãbò bò awọn ti ngbe Jerusalemu; ẹniti o ba si ṣe ailera ninu wọn li ọjọ na yio dabi Dafidi; ile Dafidi yio si dabi Ọlọrun, bi angeli Oluwa niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì; ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì OLÚWA níwájú wọn.