Zechariah 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kọjá kúrò ni ilẹ̀ náà.