Zechariah 14:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba.