Zechariah 14:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá yóò wà láàrin wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ ìkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ ìkejì rẹ̀.