Zechariah 14:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi idile Egipti kò ba si goke lọ, ti nwọn kò si wá, ti kò ni òjo; àrun na yio wà, ti Oluwa yio fi kọlù awọn keferi ti kò goke wá lati pa àse agọ na mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; àrùn náà yóò wà, tí OLÚWA yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà