Zechariah 14:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni “MÍMỌ́ SÍ OLÚWA” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé OLÚWA yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.