Zechariah 14:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalemu ati ni Juda yio jẹ mimọ́ si Oluwa awọn ọmọ-ogun: ati gbogbo awọn ti nrubọ yio wá, nwọn o si gbà ninu wọn, nwọn o si bọ̀ ninu rẹ̀: li ọjọ na ni ara Kenaani kì yio si si mọ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jérúsálẹ́mù àti ni Júdà yóò jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rubọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kénánì kò ní sí mọ́ ni ile OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.