Zechariah 14:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ó sì ṣá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Àṣàlì: nítòòtọ́, ẹ̀yin ó ṣá bí ẹ tí ṣá fún ìmímì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Úṣáyà ọba Júdà: OLÚWA Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni-mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.