Zechariah 14:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ; ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.