Zechariah 2:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ikogun fún iránṣẹ́ wọn: ẹ̀yín yóò sì mọ̀ pé, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.