Zechariah 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA si wí fún Sátanì pé, “OLÚWA bá ọ wí ìwọ Sátanì; àní OLÚWA tí ó ti yan Jérúsálẹ́mù, yóò bá ọ wí, igi inà kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”