Zechariah 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.” Ó sì wí fún Jóṣúà pé, “Wòó, mo mú kí àìṣedéédé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”