Zechariah 3:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní àyè láti rìn láàrin àwọn tí ó dúró yìí.