Zechariah 3:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; lori okuta kan ni oju meje o wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu aiṣedẽde ilẹ na kuro ni ijọ kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí kíyèsí i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Jóṣúà; lórí òkúta kán ni ojú méje wà: kíyèsí i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.