Zechariah 4:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Mo si wipe, mo wò, si kiyesi i, ọ̀pa fitilà ti gbogbo rẹ̀ jẹ wurà, pẹlu kòjo rẹ̀ lori rẹ̀, pẹlu fitilà meje rẹ̀ lori rẹ̀, ati àrọ meje fun fitilà mejeje, ti o wà lori rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsí i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: