Zechariah 5:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀.