Zechariah 5:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o mu u jade, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, yio si wọ̀ inu ile olè lọ, ati inu ile ẹniti o ba fi orukọ mi bura eke: yio si wà li ãrin ile rẹ̀, yio si run u pẹlu igi ati okuta inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èmi o mú un jáde,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi ọrúkọ mi búra èké: yóò si wà ni àárin ilé rẹ̀, yóò si rún un pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”