Zechariah 5:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, obinrin meji jade wá, ẹfũfu si wà ninu iyẹ wọn; nitori nwọn ni iyẹ bi iyẹ àkọ: nwọn si gbe òṣuwọn efa na de agbedemeji aiye on ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run.