Zechariah 6:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o jìna rére yio wá ikọle ni tempili Oluwa, ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rán mi si nyin. Yio si ri bẹ, bi ẹnyin o ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́ nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA, ẹ̀yiń o sì mọ̀ pé, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yín o bá gbà ohùn OLÚWA, Ọlọ́run yín gbọ́ nítootọ́.”