Zechariah 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú OLÚWA gbogbo ayé.