Zechariah 6:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé.