Zechariah 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sé àyà wọn bí òkúta ádámáńtì, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá: ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ ogun wá.