Zechariah 7:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ìjì líle tí ń fọ́n nǹkan káàkiri bẹ́ẹ̀ ni mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì. Ilẹ̀ dáradára tí wọ́n fi sílẹ̀ di ahoro, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si fi ãja tú wọn ka si gbogbo orilẹ-ède ti nwọn kò mọ̀. Ilẹ na si dahoro lẹhin wọn, ti ẹnikẹni kò là a kọja tabi ki o pada bọ̀: nwọn si sọ ilẹ ãyò na dahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dáhoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjà tàbí kí ó padà bọ̀: wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dáhoro.’ ”