Zechariah 7:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati bá awọn alufa ti o wà ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati awọn woli sọ̀rọ, wipe, Ki emi ha sọkun li oṣù karun, ki emi ya ara mi sọtọ, bi mo ti nṣe lati ọdun melo wonyi wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù kárùnún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”