Zechariah 8:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ṣáájú àkókò náà, kò sí owó iṣẹ́ fún eniyan tabi ẹranko, eniyan kò sì lè rin ìrìn àjò láìléwu; nítorí àwọn ọ̀tá tí wọ́n wà káàkiri, nítorí mo mú kí olukuluku lòdì sí ẹnìkejì rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori pe ṣãju ọjọ wọnni ọya enia kò to nkan, bẹni ọ̀ya ẹran pẹlu; bẹ̃ni kò si alafia fun ẹniti njade lọ, tabi ẹniti nwọle bọ̀, nitori ipọnju na: nitori mo doju gbogbo enia olukuluku kọ aladugbo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀.