Zechariah 8:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori irugbin yio gbilẹ: àjara yio so eso rẹ̀, ilẹ yio si hù ọ̀pọlọpọ nkan rẹ̀ jade, awọn ọrun yio si mu irì wọn wá: emi o si mu ki awọn iyokù enia yi ni gbogbo nkan wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èṣo rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí.