Zechariah 8:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò ṣi ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrin àwọn aláìkọlà, ẹ̀yin ilé Júdà, àti ilé Íṣrẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”