Zechariah 8:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà; nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà.”