Zechariah 8:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”