Zechariah 8:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù: Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́; àti òkè-ńlá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́.”