Zechariah 8:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ ṣara gírí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii tí ń sọ láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí ẹ baà lè kọ́ ilé náà parí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì.