Zechariah 9:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu, òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu, a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun. Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia, ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Éfúráímù, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jérúsálẹ́mù, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn aláìkọlà. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti òkun dé òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.