Zechariah 9:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi, mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀. Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà, láti pa àwọn ará Giriki run, n óo sì fi tagbára tagbára lò yín bí idà àwọn jagunjagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó fa Júdà le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Éfúráímù kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Ṣíónì, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Gíríkì, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.