Zechariah 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀. Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn, wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ, tí a dà sórí pẹpẹ, láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n; wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.