Zechariah 9:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n, bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀. Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀, bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.