Zechariah 9:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó? Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ore rẹ̀ ti tobi to, ẹwà rẹ̀ si ti pọ̀ to! ọkà yio mu ọdọmọkunrin darayá, ati ọti-waini titún yio mu awọn ọdọmọbinrin ṣe bẹ̃ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.