Zechariah 9:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi, àti Ékírónì: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í. Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀, Ásíkélónì yóò sì di ahoro.