Zephaniah 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘OLÚWA kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’