Zephaniah 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo mú hílàhílo bá ọmọ eniyan, kí wọ́n baà lè rìn bí afọ́jú. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóo ṣàn dànù bí omi, a óo sì sọ ẹran ara wọn nù bí ìgbẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu ipọnju wá bá enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitori nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa: ẹjẹ̀ wọn li a o si tú jade bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLÚWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.