Zephaniah 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn agbo ẹran yóo dùbúlẹ̀ láàrin rẹ̀, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ igún ati òòrẹ̀ yóo sì máa gbé inú olú-ìlú rẹ̀. Ẹyẹ òwìwí yóo máa dún lójú fèrèsé, ẹyẹ ìwò yóo máa ké ní ibi ìpakà wọn tí yóo dahoro; igi kedari rẹ̀ yóo sì ṣòfò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ṣíbẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá ní orísìírísìí. Òwìwí ihà àti dídún bí ẹyẹ òwìwí yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀. Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé, ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu ọ̀nà, òun yóò sì ṣẹ́ kédárì sílẹ̀.