Zephaniah 2:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìlú tí ó jókòó láìléwu, tí ń fọ́nnu wí pé, “Kò sí ẹlòmíràn mọ́, àfi èmi nìkan.” Wá wò ó, ó ti dahoro, ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹranko burúkú! Gbogbo àwọn tí wọn ń gba ibẹ̀ kọjá ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni ilu alayọ̀ na ti o ti joko lainani ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹnikan ti mbẹ lẹhìn mi: on ha ti ṣe di ahoro bayi, ibùgbe fun ẹranko lati dubulẹ si! olukuluku ẹniti o ba kọja lọdọ rẹ̀ yio pòṣe yio si mì ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu. Ó sì sọ sí ara rẹ̀ pé, “Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.” Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìnín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.