Zephaniah 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Júdà, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí ìjẹ fún ẹran, Ní ilé Áṣíkélónì ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. OLÚWA Ọlọ́run wọn yóò bojútó wọn, yóò sì yí ìgbékùn wọn padà.