Zephaniah 2:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni OLÚWA Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, “Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómù àti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà, ibi tí ó kún fún yèrèpè àti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”