Zephaniah 3:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo ìsẹ́ni tí ó ti ṣe sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.