Zephaniah 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iyokù Israeli kì yio hùwa ibi, bẹ̃ni nwọn kì yio sọ̀rọ eke, bẹ̃ni a kì yio ri ahọn arekerekè li ẹnu wọn: ṣugbọn nwọn o jẹun nwọn o si dubulẹ, ẹnikan kì yio si dẹ̀ruba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rù bà wọ́n.”