Zephaniah 3:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín, n óo gba àwọn arọ là, n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ. N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba atiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.